Monday, September 8, 2014

Introduction of Guests : The Hymn YMHB 765



1.    INTRODUCTION OF GUESTS : Introduction of New Patrons, Patronesses, Advisers and Awards

2.    THE HYMN YMHB 765 (Collection for Circuit Development)

1.    Oluwa orun on aiye,
‘Wo n’ iyin at’ ope ye fun;
Bawo l’a ba ti fe O to,
Ibu ore?

2.    Orun tin ran, at’ afefe
Gbogbo eweko nso ‘fe Re
‘Wo l’o nmu irugbin dara,
Ibu ore.

3.    Fun ara lile wa gbogbo,
Fun gbogbo ibukun aiye,
Awa sope, a sin yin O,
Ibu ore.

4.    O ko du wa li Omo Re,
O fi fun aiye ese yi,
Pelu Re, lofe l’ O nfun wa
L’ ohun gbogbo.

5.    O fun wa l’ Emi Mimo Re,
Emi iye at’ agbara,
O nrojo ekun ‘bukun Re
Le wa lori.

6.    Fun idariji ese wa,
Ati fun ireti orun,
Kil’ ohun t’a ba fi fun O,
Ibu ore?

7.    Owo ti a nna, ofo ni,
Sugbon isura tit’ aiye
L’ eyi t’a bun O, Oluwa,
Ibu ore.

8.    Ohun t’a bun O, Oluwa,
‘Wo o san le pada fun wa;
L’ ayo l’a o ta O l’ ore,
Ibu ore, -

9.         Iwo t’a t’ odo Re dide,
            T’ awa – t’ ebun on ini wa;
            Jek’ a le ba O gbe titi,
            Ibu ore!.
            Amin.


Adesegun Akitoye
http://spiritualhymnsong.blogspot.com

No comments:

Post a Comment

Roll Call of Members Alphabets T, W, X, Y & Z at 2024 Family Reunion Thanksgiving at Wesley Cathedral Olowogbowo

Alphabets T, W, X, Y, Z The N. A. B. Thomas Family The Adeoye Thomas Family The Kemi Thomas Family The Strack/Tay Family The B. K. Tandoh Fa...