Monday, March 3, 2014

Iwa rere l' Oluwa fe wa fun



Iwa rere l’Oluwa fe wa fun

1.            Iwa rere l’Oluwa fe wa fun
Ona rere l’Olorun fe julo;     (2ce)
Opo enia l’O ti l’owo lowo ri, ranti o,
Ranti igbehin Oloro ati Lasaru;
Iwa rere l’Olorun fe julo.

2.            Hu ‘wa rere tori ojo ale
Gb’ ero rere tori atisun o;  (2ce)
Opo enia l’o ti l’ola l’ola ri, ranti o,
Ranti igbehin Oba na “Nebkadnezari”;
Hu ‘wa rere tori atisun o.

3.            Gb’ imo rere tori ojo ogbo,
S’eto rere f’ojo ikehin o;     (2ce)
Opo enia l’o ti l’omo l’owo ri, ranti o,
Ranti igbehin Eli at’ awon omo re;
S’ eto rere f’ojo ikehin o.

4.            Baba Mimo, jowo pale wa mo,
Pese fun wa, Baba, a mbe o; (2ce)
La ona iye fun wa titi lailai, Oluwa;
Jek’ a le t’ona Re d’opin, Baba, dakun o,
Baba Mimo, jowo fi wa pamo.


 Adesegun Akitoye
http://www.homebusinessassurance.com



Enia Dudu, E je ka se rere o



Enia Dudu, E je ka se rere o

1.            Enia dudu, e je ka se rere o
Ijo Methodist, e je ka se rere o (2ce)
T’a ba se rere aiye a ye wa
T’a ba sere orun wa asunwon
Enia se rere o (2ce)
Nitori ati sun re o, se rere
Se re (2ce)
Nitori ati sun re o, se rere.



2.            Enia dudu, e je ka ma s’ ore o
Ijo Methodist, e je ka ma s’ ore o (2ce)
T’a ba s’ ore aiye a ye wa
T’a ba ns’ ore, orun wa asunwon
Enia se rere o (2ce)
Nitori ati sun re o, se rere
Se re (2ce)
Nitori ati sun re o, se rere.

3.         Enia dudu, e je ka sin baba o
Ijo Methodist, e je ka sin baba o (2ce)
T’a ba sin Baba aiye a ye wa
T’a ba sin Baba, orun wa asunwon
Enia se rere o (2ce)
Nitori ati sun re o, sin Baba
Sin Baba
Nitori ati sun re o, sin Baba.


Adesegun Akitoye
http://www.homebusinessassurance.com
 

E yo Jesu Joba : YMHB 591



1.            Orin YMHB 591 – E yo Jesu joba

1.    E yo Jesu joba
N’nu omo enia:
O da ara tubu,
O so won d’ omnira:
B’ Esu koju s’ Om’ Olorun
L’ aif’ ota pe, ise Re nlo.

2.    Ise ti ododo,
Oto, alafia,
Yio tan kakiri
Fun ‘rorun aiye wa,
Keferi, Ju, nwon o wole
Nwon o jewo isin yiye.

3.    Agbara l’owo Re
Fun abo eni Re;
Ase titobi Re
L’ opo o kiyesi;
Orun f’aye wo ise Re,
Erekusu gbo ofin Re.

4.    Irugbin t’ orun y,
O fere d’ igi nla;
Abukun ‘wukara
Ko le s’ aitan kiri,
Tit’ igba t’ Olorun Omo
Yio tun pada wa. Amin.


Adesegun Akitoye
http://www.homebusinessassurance.com
 

Gbogbo ise Oluwa : By A. K. Ajisafe



1.            Orin – Gbogbo ‘se Oluwa – A. K. Ajisafe

1.    Gbogbo ‘se Oluwa, f’ibukun f’Oluwa
Gbogbo Eda Orun, f’ibukun f’Oluwa,
Gbogbo Eda Aiye, E f’ibukun f’Oluwa
K’e yin k’e si ma gbe ga titi lae.

2.    Gbogbo Eiye oju orun, f’ibukun f’Oluwa
Gbogbo ohun t info loke, f’ibukun f’Oluwa
Enyin Eranko igbe : E f’ibukun f’Oluwa
K’e yin k’e si ma gbe ga titi lae.

3.    Enyin Angeli Oluwa, f’ibukun f’Oluwa
Enyin orun at’ osupa, f’ibukun f’Oluwa
Enyin ‘Rawo oju orun, E f’ibukun f’Oluwa
K’e yin k’e si ma gbe ga titi lae.

4.    Enyin Efufu oju orun, f’ibukun f’Oluwa,
Enyin osan at’ orun, f’ibukun f’Oluwa
Enyin ojo at’ erun : E f’ibukun f’Oluwa
K’e yin k’e si ma gbe ga titi lae.

5.    K’omode at’ agba, f’ibukun f’Oluwa
Gbogbo Egbe inu Ijo, f’ibukun f’Oluwa,
L’okunrin l’obinrin : E f’ibukun f’Oluwa
K’e yin k’e si ma gbe ga titi lae.

6.    Enyin Akorin Oluwa : f’ibukun f’ Oluwa,
Enyin Bishop Ijo Eleto, f’ibukun f’Oluwa
Gbogbo Enyin Alufa Oluwa : E f’ibukun f’Oluwa
K’e yin k’e si ma gbe ga titi lae.

GLORIA : Ogo fun Metalokan

Baba, Omo, Emi o, Eni aiyeraiye o,
Baba, Omo, Emi o, Iyin ti ko lopin.
Lao fi juba Re, Iyin ti ko lopin,
Lao fi juba Re : Titi aiye ainipekun
Amin o, Amin, Ase : Amin o, Amin Ase
Amin o, Amin Ase. Titi aiye ainipekun
Amin o, Amin, Ase. (Ase).


Adesegun Akitoye
http://www.homebusinessassurance.com
 

Roll Call of Members Alphabets T, W, X, Y & Z at 2024 Family Reunion Thanksgiving at Wesley Cathedral Olowogbowo

Alphabets T, W, X, Y, Z The N. A. B. Thomas Family The Adeoye Thomas Family The Kemi Thomas Family The Strack/Tay Family The B. K. Tandoh Fa...