Iwa
rere l’Oluwa fe wa fun
1.
Iwa
rere l’Oluwa fe wa fun
Ona rere l’Olorun fe julo; (2ce)
Opo enia l’O ti l’owo lowo ri, ranti o,
Ranti igbehin Oloro ati Lasaru;
Iwa rere l’Olorun fe julo.
2.
Hu
‘wa rere tori ojo ale
Gb’ ero rere tori atisun o; (2ce)
Opo enia l’o ti l’ola l’ola ri, ranti o,
Ranti igbehin Oba na “Nebkadnezari”;
Hu ‘wa rere tori atisun o.
3.
Gb’
imo rere tori ojo ogbo,
S’eto rere f’ojo ikehin o; (2ce)
Opo enia l’o ti l’omo l’owo ri, ranti o,
Ranti igbehin Eli at’ awon omo re;
S’ eto rere f’ojo ikehin o.
4.
Baba
Mimo, jowo pale wa mo,
Pese fun wa, Baba, a mbe o; (2ce)
La ona iye fun wa titi lailai, Oluwa;
Jek’ a le t’ona Re d’opin, Baba, dakun o,
Baba Mimo, jowo fi wa pamo.
Adesegun Akitoye
http://www.homebusinessassurance.com
No comments:
Post a Comment