MESSAGE
11. HYMN YMHB
374 (Relief Fund)
1.
Jesu,
mo gb’ agbelebu mi,
Ki nle ma to O lehin;
Mo tosi, mo j’ eni-egan,
Wo l’ ohun gbogbo fun mi.
Bi gbogbo ini mi segbe,
Ti ero mi gbogbo pin;
Sibe mo ti loro po to!
Temi l’ Olorun l’ orun.
2.
B’
aiye kegan t’o si ko mi,
Nwon ko Olugbala ri;
B’ ore da mi, t’a tan mi je,
‘Wo ki s’ eletan bi won:
Bi inu Re ba dun si mi,
‘Wo Ogbon, Ife, Ipa,
‘Rira enia ko je nkan;
Si oju Re, ayo de.
3.
Eda
le ma wahala mi,
Y’o mu mi sunmo O ni;
Idanwo aiye le ba mi,
Orun y’o mu ‘simi wa.
Ibanuje ko le pa mi,
B’ Iwo ba fe mi sibe!
Ayo mi ko si le ladun,
B’ Iwo ko ba si n’nu re!
4.
Emi
mi, gba igbala re;
Bori ese at’ eru:
F’ ayo wa ni ipokipo,
Ma sise, si ma jiya,
Ranti Emi ti ngbe ‘nu re,
At’ ife Baba si o,
Olugbala t’ o ku fun o:
Om’ orun, ‘wo iba kun?
5.
Ma
nso lat’ or’-ofe s’ ogo,
N’nu ‘gbagbo on adura;
Aiyeraiye mbe n’ waju re;
Baba y’o mu o de ‘be.
Ise re l’ aiye fe buse,
Irin-ajo fe dopin,
Laipe, ireti y’o d’ oto,
Adura y’o d’ orin ‘yin.
Amin.
Adesegun Akitoye
http://www.homebusinessassurance.com
No comments:
Post a Comment