Saturday, January 18, 2014

Kini ngo fun Olorun mi : Hymn YMHB 288



1.    Hymn YMHB 288

1.    Kini ngo fun Olorun mi
Fun gbogbo anu Re?
Ngo gba ebun Re, ngo si fi
Irele bere si.

2.    Ago or’-ofe igbala
L’ emi o f’ ope gba,
Ngo fehinti ileri Re,
Ngo si wa f’ ogo Re.

3.    Loju awon enia Re
Ni ngo san eje mi,
Ngo f’ ara mi on ini mi
Fi josin f’ Olorun.

4.    Baba, gbogb’ ohun ti mo ni,
‘Wo l’ o fi jinki mi;
Mo je omo Re laiye yi,
‘Wo si ra mi pada.

5.    Owo Re l’ o da mi, l’ o si
Da mi n’de n’nu ese;
Anu Re t’o tu ide mi
Si ti de mi mo O.

6.    Olorun Oludande mi,
Ngo ma kokiki Re,
Emi y’o ru ebo iyin,
Ngo kepe oko Re.

7.    E f’ iyin f’ Olorun ife
T’ o f’ ese mi ji mi,
Titi ao pelu ‘jo toke
Ko orin ti orun.


Adesegun Akitoye
http://www.homebusinessassurance.com
 


No comments:

Post a Comment

COMMITTAL / FOR AS SUCH AS YOUR SERVANT, MRS. VICTORIA OLAMIDE WILLIAMS DEPARTED

COMMITTAL   We know that if the earthly house of our tabernacle be dissolved, we have a building from God, a house not made with hands, ...